MediaWiki:Prefswitch-main/yo

From translatewiki.net
Àwọrán ojúìran ìtọ́ka ìfojúkojú Wikipedia tuntun (nígbàngbà)
Àwọrán ojúìran ìfojúkojú àtúnṣe ojúewé (nígbàngbà)
Àwọrán ojúìran pátákó àkíyèsí tuntun fún àwọn ìjápọ̀

Ẹgbẹ́ Ìrírí Oníṣe Wikimedia Foundation ti únṣiṣẹ́ pẹ̀lú àwọn afìfẹ́ṣe láti àgbàjọ láti múu dẹ̀rọ̀ fun yín. Inú wa dùn láti fún yín ní àwọn ìmúdára wọ̀nyí bíì iwojú àti ìṣiṣẹ́ tuntun àti àwọn ìní àtúnṣe ṣíṣọdẹ̀rọ̀. Àwọn ìyípadà tuntun wọ̀nyí wáyé láti jẹ́ kí ó dẹ̀rọ̀ fún àwọn olùfikún tuntun láti bẹ̀rẹ̀, wọ́n sì jẹ́ lórí ìdánwò ìṣeémúlò wa tó wáyé ní ọdún tó kọjá. Mímúdára ìseémúlò àwọn iṣẹ́-ọwọ́ wa ni ohun tó jẹ Wikimedia Foundation lógún bẹ́ẹ̀sìni a ó fun yín nk ọ̀pọ̀ àwọn ìṣọdọ̀tun lọ́jọ́ iwíjú. Fún àwọn ẹ̀kúnrẹ́rẹ́, ẹ ṣèbẹ̀wò sí àgbéjade blog Wikimedia tó yẹ.

Àwọn àtúnṣe tó wáyé nìyí

  • Ìtọ́ka: A ti ṣèmúdára ìtọ́ka fún kíkà àti títúnṣe àwọn ojúewé. Nísinyìí, àwọn ìpele lórí ojúewé kọ̀ọ̀kan fihàn kedere dáadáa bóyá ẹ únwo ojúewé òhún tàbí ojúewé ìfọ̀rọ̀wérọ̀ rẹ̀, àti bóyá ẹ ùnkà tàbí ẹ ùnṣàtúnṣe ojúewé náá.
  • Àwọn ìmúdára ìpele irinṣẹ́ ìṣàtúnṣe: A ti ṣàtúngbájọ ìpele irinṣẹ́ ìṣàtúnṣe láti jẹ́ kó rorùn fún lílò. Nísinyìí, Ìṣèdá àwọn ojúewé ti dẹ̀rọ̀ ó sì lóye.
  • Olùrànwọ́ ìjápọ̀: Irinṣẹ́ tó dẹ́rọ̀ láti lò úngbàyín láyè láti ṣàfikún ìjápọ̀ sí àwọn ojúewé wiki míràn àti bákannáà ìjápọ̀ sí àwọn ibi ìtakùn òde.
  • Àwọn ìmúdára ìṣàwárí: A ti ṣàmúdára àwọn ìmọ̀ràn ìṣàwárí láti mú yín lọ sí ojúewé tí ẹ únwá kíákíá.
  • Àwọn ìní tuntun míràn: A tún ti ṣe olùránwọ́ tábìlì láti mú dídá tábìlì dẹ̀rọ̀ àti ọ̀nà síṣèrọ́pọ̀ nínú àtúnṣe ojúewé.
  • Àmì-iléiṣẹ́ Wikipedia: A ti ṣọdọ̀tun àmì-iléiṣẹ́ wa. Ẹ kà nípa rẹ̀ lórí blog Wikimedia.